Àṣẹ láti san owó orí
Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú. Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo. Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀. (Romu 13:5-7)
Jesu fọwọ́ sí sísan owó orí
Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?” Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Matiu 22:17-21)
Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un? Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀. (Marku 12:14-17)
Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?” Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Luku 20:22-25)
Àpẹẹrẹ owó orí tí a san
Nísinsin yìí Meṣa ọba Moabu ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Israẹli pẹ̀lú ọ̀kẹ́ márùn-ún ọ̀dọ́-àgùntàn àti pẹ̀lú irun ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àgbò. (2 Ọba 3:4)
Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́. (2 Ọba 15:20)
Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan. Jehoiakimu sì san fún Farao Neko fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín. (2 Ọba 23:33, 35)
Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí. Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró. (Esra 6:8)
Èrè àkànṣe – a kò béèrè owó orí
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli wí pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò rí i bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá? Ó jáde wá láti pe Israẹli níjà. Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀. Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Israẹli.” (1 Samuẹli 17:25)
A kò béèrè owó orí/owó ìṣákọ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi
Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sísan owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí. (Esra 7:24)
Jesu san owó orí tẹ́ńpìlì kí ó má baà mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀
Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?” Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.” Nígbà tí Peteru wọ ilé láti bá Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.” Jesu sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó òde? Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.” (Matiu 17:24-27)
Àpẹẹrẹ owó ìṣákọ́lẹ̀ tí a san
Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. (1 Ọba 4:21)
Ní ọdún kejìlá ọba Ahasi ará Juda, Hosea ọmọ Ela jẹ ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ fún ọdún mẹ́sàn-án. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i ti ọba Israẹli ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀. Ṣalamaneseri ọba Asiria wá sókè láti mú Hosea, ẹni tí ó ti jẹ fún Ṣalamaneseri ó sì ti san owó òde fún un. (2 Ọba 17:1-3)
Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀. (2 Kronika 17:5)
Jehoṣafati sì ń di alágbára nínú agbára sí i, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìṣúra púpọ̀ ní Juda (2 Kronika 17:12)
Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) òsùwọ̀n alikama àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta. (2 Kronika 27:5)
Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti tálẹ́ǹtì wúrà kan. (2 Kronika 36:3)
Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn. (Esra 4:20)
Ìhalẹ̀ nígbà tí a kò san owó ìṣákọ́lẹ̀
Síwájú sí i, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù. (Esra 4:13)