Òtítọ́

Ìwé Mímọ́ gbà pé ọkàn ènìyàn kò ní òtítọ́, ó sì fúnni ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ìwà àìṣòótọ́. Ọlọ́run ń béèrè òtítọ́ pípé nínú gbogbo apá ìgbésí ayé, ó sì fi bí a ṣe lè ṣẹ́gun àìṣòótọ́ àti bí a ṣe lè tún àjọṣe tí ó bàjẹ́ ṣe hàn.

Ènìyàn kì í ṣe olóòótọ́

Ọkàn ènìyàn kì í ṣe olóòótọ́

Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. (Gẹnẹsisi 8:21)
Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè wòsàn. Ta ni èyí lè yé? (Jeremiah 17:9)
Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. (Matiu 15:19)
Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara-ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. (Marku 7:21-22)

Ènìyàn ń ṣe òtítọ́ díẹ̀díẹ̀ ni

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́. (Onidajọ 17:6)

Àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn aláìṣòótọ́

...síbẹ̀síbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára. (Gẹnẹsisi 31:7)
Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí, nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.” (Joṣua 7:11, 20-21)
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po. (1 Samuẹli 8:3)
Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ” (1 Ọba 21:19)
Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà, lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké. (Saamu 58:3)
Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn. (Isaiah 1:23)
Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀; wọn kì í ní ànító. Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye; olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀. (Isaiah 56:11)
“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn. (Jeremiah 6:13)
“ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ? Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí. (Jeremiah 7:9, 11)
Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo. (Esekiẹli 22:27, 29)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́, Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà, àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀. (Hosea 4:1-2)
Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi. (Hosea 5:10)
...nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta. Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn, àwọn olè ń fọ́ ilé; àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà; (Hosea 7:1)
Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. (Hosea 12:7)
Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀, àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú? Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn? Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn? (Mika 6:10-12)
Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́. (Johanu 12:4-6)
Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba. (Johanu 18:40)
Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan. Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?” Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín. Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.” Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.” Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀. (Ìṣe àwọn Aposteli 5:1-10)
Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé. “Òpùrọ́ ní àwọn ará Krete, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, àti oníwọra”. (Titu 1:12)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbèrè wọn, tàbí olè wọn. (Ìfihàn 9:20-21)

Òwe tí ó lo àìṣòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ

Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’ “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe. Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’ “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’ “Ó sì wí pé, ‘Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) òsùwọ̀n òróró.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta lé ní irinwó (450).’ “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ?’ “Òun sì wí pé, ‘Ẹgbẹ̀rún (1,000) òsùwọ̀n alikama.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ẹgbẹ̀rin (800).’ “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é, àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. (Luku 16:1-8)

Àìṣòótọ́ tí a fi ẹ̀sìn bò

“ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ? Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” àwa yè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyí bí? Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí. (Jeremiah 7:9-11)
Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé. Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.” (Matiu 21:12-13)
“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. (Matiu 23:25)
Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.” (Marku 11:15-17)
Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ. (Luku 11:39)
Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọ́ṣà.” (Luku 19:45-46)
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, asọ̀rọ̀ asán àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrín àwọn onílà. Ó gbọdọ̀ pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wọ́n ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ère àìṣòdodo. (Titu 1:10-11)

Ọlọ́run ń béèrè òtítọ́ pípé

Olúwa ni òtítọ́, Satani jẹ́ òpùrọ́

Olúwa ni òtítọ́

Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́. (Johanu 1:14)
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. (Johanu 14:6)
Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo, nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ, yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín. (Johanu 16:13)
Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí. (1 Johanu 5:7)

Satani jẹ́ òpùrọ́

Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. (Johanu 8:44)

Lábẹ́ òfin Májẹ̀mú Láéláé

Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. (Eksodu 20:15)
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì. (Lefitiku 19:11-13)
“ ‘Ẹ má ṣe lo òsùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òsùwọ̀n ọ̀pá, òsùwọ̀n ìwúwo tàbí òsùwọ̀n onínú. Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti. (Lefitiku 19:35-36)
“ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ. Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tókù láti kórè. Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀. Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. (Lefitiku 25:14-17)
Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. (Deuteronomi 5:19)
Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní. (Deuteronomi 19:14)
Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo. (Deuteronomi 25:13-16)

Gẹ́gẹ́ bí ìlànà Bíbélì gbogbogbòò

Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ. (Saamu 34:13)
Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú; ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀. (Saamu 51:6)
Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn. (Saamu 62:10)
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ. (Òwe 3:3)
Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ. (Òwe 4:24)
Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, (Òwe 6:12)
Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i, ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan. (Òwe 6:16, 19)
Olúwa kórìíra òsùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀. (Òwe 11:1)
Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. (Òwe 12:22)
Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú. (Òwe 13:5)
Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde. (Òwe 14:5)
Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn. (Òwe 14:25)
Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè, bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé! (Òwe 17:7)
Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀. (Òwe 16:11)
Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì. (Òwe 20:10)
Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. (Òwe 20:23)
Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè, nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà. (Òwe 22:22-23)
Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì, tí àwọn baba rẹ ti pa. (Òwe 22:28)
Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò; má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba. (Òwe 23:10)
Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á; ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye. (Òwe 23:23)
Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,” irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run. (Òwe 28:24)
Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ, láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀. (Ẹkún Jeremiah 3:35-36)
Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí. (Sekariah 8:16-17)
Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.” Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.” (Luku 3:12-14)
Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? (Romu 2:21-22)
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọrinti 6:7-10)
Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. (Efesu 4:25)
Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. (Efesu 6:14)
Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, (Kolose 3:9)
Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi. (1 Tẹsalonika 5:22)
Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro. (1 Timotiu 1:9-10)
Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere. (Titu 2:9-10)
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!” (1 Peteru 1:15-16)
Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. (1 Peteru 4:15)

A béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olórí

Ìjọba

Ṣa àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ; yàn wọ́n ṣe olórí, lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá. Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèké. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe. (Eksodu 18:21-22)
Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu. (Òwe 20:28)
Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́. (Òwe 28:16)
“ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí. Kí ẹ̀yin kì ó lo òsùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́. (Esekiẹli 45:9-10)

Ìjọ

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò. (1 Timotiu 3:8)
Alábojútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò. (Titu 1:7)
Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn. Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. (1 Peteru 5:1-2)

A béèrè òtítọ́ nínú fífúnni

Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. (Malaki 1:13-14)

Àìfúnni bí ó ti yẹ jẹ́ olè jíjà

“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè. (Malaki 3:8-9)

Òtítọ́ níye lórí ju ọrọ̀ lọ

Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. (Òwe 19:1)
Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ. (Òwe 19:22)
Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora. (Òwe 28:12)

Àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ènìyàn

Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!” (Numeri 16:15)
Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.” Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.” Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.” (1 Samuẹli 12:3-5)
“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn, ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu. (Jobu 31:5, 8)
Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara. (Daniẹli 6:4)
Ọlọ́run mi rán angẹli i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pa mí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.” (Daniẹli 6:22)
Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké. Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.” (Sefaniah 3:13)

Àpẹẹrẹ dídán òtítọ́ àwọn ènìyàn wò

Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run. Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má ba à kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí. (Gẹnẹsisi 42:11, 18-20)
Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò. Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’ “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn. Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ” (Gẹnẹsisi 42:31-34)

Àwọn olùfọkànsìn kórìíra àìṣòótọ́

Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú. (Òwe 13:5)

Èéṣe tí Ọlọ́run fi ń béèrè òtítọ́ pípé?

A kò lè jẹ́ aláìṣòótọ́ ká sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa. (Òwe 14:2)

A kò lè jẹ́ aláìṣòótọ́ ká sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa

Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà, ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run. (Òwe 26:28)
Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀, nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin. (Romu 13:9-10)

Òtítọ́ ń jẹ́ kí ìwàásù ìhìnrere ní ìgbẹ́kẹ̀lé

Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé. (Filipi 2:15)

Òtítọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti darí ìgbésí ayé wa

Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á. Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan. (Òwe 4:24-26)

Kódà àìṣòótọ́ tí ó kéré jù lọ ń ṣe ìpalára

“Ẹni tí ó bá ṣe olóòtítọ́ nínú ohun kínkínní, ó ṣe olóòtítọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkínní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú. (Luku 16:10)

Báwo ni a ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìdẹwò àìṣòótọ́?

Nípa oore-ọ̀fẹ́ àti agbára Olúwa

Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́. (Saamu 119:36)
“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú. Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan. (Òwe 30:7-8)
Ǹjẹ́ mo ní, ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara, àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. (Galatia 5:16-17)

Nípa títẹ̀lé òfin wúrà

Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì. (Matiu 7:12)
Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú. (Filipi 2:4)

Nípa ìbẹ̀rù Olúwa tí ó dára

Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi. (Òwe 16:6)

Yíya ara wa sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìṣòótọ́

Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé. (Saamu 26:4)
Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn. (Saamu 40:4)
Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí. Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi. (Saamu 101:6-7)
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí; jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò; a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa, da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,” ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. (Òwe 1:10-16)
Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀, ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn. (Òwe 29:24)
Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn. Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun. (1 Kọrinti 5:9-11)
Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.” (1 Kọrinti 15:33)

Nípa fífúnni

Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní. (Efesu 4:28)

Nípa gbígbé ètò ìjíhìn kalẹ̀

Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn. Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi. Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí gbé.” (Gẹnẹsisi 30:31-33)

Kí ni a ó ṣe nígbà tí a bá ti hùwà àìṣòótọ́?

Mú ìdàpọ̀ wa pẹ̀lú Olúwa padà bọ̀ sípò

Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀ àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú wa fún Olúwa, abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀. (Lefitiku 5:5-6)
Olúwa sọ fún Mose pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀. Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he, tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú Olúwa, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.” (Lefitiku 6:1-5, 7)
Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. (1 Johanu 1:9)

Mú àjọṣe wa pẹ̀lú ẹni tí a ṣe lóṣé padà bọ̀ sípò

Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà. (Òwe 28:13)
Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀. (Jakọbu 5:16)

Dá ohunkóhun tí a jí padà

“Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí. “Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà. Bí a bá rí ẹran tí ó jí gbé náà ni ọwọ́ rẹ̀ ní ààyè: ìbá ṣe akọ màlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì. (Eksodu 22:1-4)
“Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì. Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, baálé ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà. Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀. (Eksodu 22:7-9)
“Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà. (Eksodu 22:14)
Olúwa sọ fún Mose pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀. Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he, tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀. (Lefitiku 6:1-5)
Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí òun jẹ̀bi rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà. (Numeri 5:5-8)
Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.” (2 Samuẹli 12:5-6)
Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á. Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà. (Òwe 6:30-31)
Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ. Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú. A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú. (Esekiẹli 33:14-16)
Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!” (Luku 19:8)

Ìbùkún àti ègún

Ìbùkún tí a ṣèlérí fún àwọn olóòótọ́

Ìbùkún àjọṣe tí ó súnmọ́ Olúwa sí i

Saamu ti Dafidi. Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ? Ẹni tí ń rìn déédé tí ó sì ń sọ òtítọ́, láti inú ọkàn rẹ̀; tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀ tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀, ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀ àní tí kò sì yípadà, (Saamu 15:1-4)
Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké. (Saamu 24:3-4)
Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́. (Saamu 145:18)
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn. (Òwe 3:3-4)
Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin. (Òwe 3:32)
Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. (Òwe 12:22)
“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un. Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.” (Jeremiah 22:15-17)

Ìbùkún ààbò

Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé, (Òwe 2:7)
Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu, ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú. (Òwe 10:9)

Ìbùkún ìpèsè

Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi, Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú. (Isaiah 33:15-16)

Ìbùkún lórí ìdílé

Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. (Òwe 20:7)

Ìbùkún ayọ̀

Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè, ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. (Òwe 10:2)

Ìbùkún ìyè

Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. (Deuteronomi 25:13-15)
Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀; kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere? Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ. (Saamu 34:12-13)
Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. (Òwe 12:19)
Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ. Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú. A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú. (Esekiẹli 33:14-16)

Ìbùkún ọ̀wọ̀ àwọn ènìyàn

Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn. (Òwe 3:3-4)

Ìbùkún aásìkí

Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. (Òwe 15:6)

Ìbùkún fún àwọn olórí

Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́. (Òwe 28:16)

Ègún tí a pa mọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́

Ègún kíkórìíra/yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run

Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo. (Deuteronomi 25:13-16)
...ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra. (Saamu 5:6)
Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin. (Òwe 3:32)
Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i, ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan. (Òwe 6:16, 19)
Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. (Òwe 12:22)
Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun. (Òwe 19:9)
Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀. (Isaiah 57:17)
Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́. Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi. Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi. Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo; kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́; wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà. (Isaiah 59:2-4)

Ègún ìjìyà/ìdájọ́

“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!” (Deuteronomi 27:17)
Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́. (Saamu 63:11)
Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. (Òwe 12:22)
Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé. (Òwe 15:26)
Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́. (Òwe 19:5)
Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀. (Òwe 20:17)
Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀. (Isaiah 57:17)
Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára, wọ́n sanra wọ́n sì ń dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà. Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí? (Jeremiah 5:27-29)
Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òtítọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn; wọn kò sì náání mi, ní Olúwa wí. “Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ. Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́. Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,” ni Olúwa wí. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi? Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró; ó ń sọ ẹ̀tàn. Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀, ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀. Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?” (Jeremiah 9:3-9)
“ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín. Ọkàn rẹ le gbà á, tàbí ọwọ́ rẹ lè le, ní ọjọ́ tí èmi yóò bá ọ ṣé? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe é. Èmi yóò tú yin ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ. (Esekiẹli 22:13-15)
Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́. Àti àwọn wòlíì rẹ́ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì ìran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀ṣẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí,’ nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo. “Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan. Nítorí náà ni mo ṣe da ìbínú mi sí wọn lórí, mo ti fi iná ìbínú mi run wọn, mo si ti fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.” (Esekiẹli 22:27-31)
Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi. (Hosea 5:10)
Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀. Tí ẹ ń wí pé, “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró?” Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ, kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà, kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní, kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀. Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé, “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe. “Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí? Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀? Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili, yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan. Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò. (Amosi 8:4-10)
Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀, àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú? Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn? Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn? Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrín rẹ. Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà. Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ olifi, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ; ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì. Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà; ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.” (Mika 6:10-16)
Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé. Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.” (Matiu 21:12-13)
Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọ́ṣà.” (Luku 19:45-46)

Ègún ikú/ìparun

Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ” Joṣua sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí wa? Olúwa yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.” Nígbà náà ni gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tókù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná. (Joṣua 7:11, 15, 25)
...ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra. (Saamu 5:6)
Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ. Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn! Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ, yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela. (Saamu 52:3-5)
Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ. (Òwe 1:19)
Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe. (Òwe 6:12, 15)
Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. (Òwe 12:19)
Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú. (Òwe 21:6)
Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà. (Òwe 22:8)
Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè, nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà. (Òwe 22:22-23)
“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.” Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’ A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.” (Jeremiah 22:17-19)
“Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oníwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn, tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀ (tí kò sì ṣe ọ̀kan nínú gbogbo iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì): “Ó ń jẹun lójúbọ lórí òkè gíga, tí ó sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. Ó ni àwọn tálákà àti aláìní lára, ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí, o gbójú sókè sí òrìṣà, ó sì ń ṣe ohun ìríra. Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù. Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. (Esekiẹli 18:10-13, 18)
Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan. Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?” Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín. Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.” Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.” Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀. (Ìṣe àwọn Aposteli 5:1-10)

Ègún lórí ìdílé

Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè. (Òwe 15:27)
Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn. (Jeremiah 8:10)
Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é. Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀. Nítorí náà, Olúwa wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi. (Mika 2:1-3)

Ègún lórí ohun ìní

...síbẹ̀síbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi. (Gẹnẹsisi 31:7, 9)
Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè, ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. (Òwe 10:2)
Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i. (Òwe 13:11)
Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí. “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn. (Jeremiah 6:12-13)
Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè. (Jeremiah 17:11)
“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé. (Mika 4:13)

Ègún ìgbéraga

Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà. (Òwe 22:8)

Ègún lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ olórí kan

Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀. (Òwe 29:12)

Ègún ayérayé

Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.” (Ìfihàn 21:8)
Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn. (Ìfihàn 21:27)
Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké. (Ìfihàn 22:15)

Ègún ní gbogbo gbòò

“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!” (Deuteronomi 27:17)
Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀. (Òwe 20:17)
Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, ó kún fún olè, ìjẹ kò kúrò! (Nahumu 3:1)

Èrò àwọn ènìyàn pé Ọlọ́run kì í jẹ àìṣòótọ́ níyà

“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́? Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀? Wọ́n a sún àmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn. Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà. (Jobu 24:1-2, 12)

Àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Ènìyàn ń fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń ṣiṣẹ́

Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í, ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere. (Òwe 17:8)
Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò: àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle. (Òwe 21:14)

Àwọn ènìyàn búburú ń fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Saamu 26:9-10)
Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po. (Òwe 17:23)

Àpẹẹrẹ àwọn tí ó fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po. (1 Samuẹli 8:3)
Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn. (Isaiah 1:23)
Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀. (Mika 7:3)
Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí. (Matiu 28:11-15)
Bí Paulu sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Feliksi, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsin yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.” Ní àkókò yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Paulu yóò mú owó ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun ba à lè dá a sílẹ̀, nítorí náà a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkígbà, a máa bá a sọ̀rọ̀. (Ìṣe àwọn Aposteli 24:25-26)

Àṣẹ pé kí a má ṣe lọ́wọ́ nínú àbẹ̀tẹ́lẹ̀

“Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. (Eksodu 23:8)
Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. (Deuteronomi 16:19)

Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń bani jẹ́

Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni. (Oniwaasu 7:7)

Àpẹẹrẹ Olúwa tí kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Deuteronomi 10:17)

Àwọn olórí kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (2 Kronika 19:7)
Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀. (Òwe 29:4)

Àpẹẹrẹ àwọn tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.” Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.” Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.” (1 Samuẹli 12:3-5)
Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá, tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín? (Jobu 6:22)

Ìbùkún àti ègún

Àwọn tí ń fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ ẹni ègún

“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!” (Deuteronomi 27:25)
...tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́. (Isaiah 5:23)
Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé ìlọ́po láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí. “ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín. Ọkàn rẹ le gbà á, tàbí ọwọ́ rẹ lè le, ní ọjọ́ tí èmi yóò bá ọ ṣé? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe é. Èmi yóò tú yin ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ. (Esekiẹli 22:12-15)
Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn. Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́. (Amosi 5:11-12)
Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó. Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.” Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó. (Mika 3:11-12)

Àwọn tí kì í fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ alábùkún

Saamu ti Dafidi. Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ? tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé. (Saamu 15:1, 5)
Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè. (Òwe 15:27)
Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi, Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú. (Isaiah 33:15-16)